Nwọn si wà li ọ̀na nwọn ngoke lọ si Jerusalemu; Jesu si nlọ niwaju wọn: ẹnu si yà wọn; bi nwọn si ti ntọ̀ ọ lẹhin, ẹ̀ru ba wọn. O si tun mu awọn mejila, o bẹ̀rẹ si isọ gbogbo ohun ti a o ṣe si i fun wọn, Wipe, Sá wo o, awa ngoke lọ si Jerusalemu, a o si fi Ọmọ-enia le awọn olori alufa, ati awọn akọwe lọwọ; nwọn o si da a lẹbi ikú, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ: Nwọn o si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn o si nà a, nwọn o si tutọ́ si i lara, nwọn o si pa a: ni ijọ kẹta yio si jinde. Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede si wá sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa nfẹ ki iwọ ki o ṣe ohunkohun ti awa ba bere lọwọ rẹ fun wa. O si bi wọn lẽre pe, Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin? Nwọn si wi fun u pe, Fifun wa ki awa ki o le joko, ọkan li ọwọ́ ọtun rẹ, ati ọkan li ọwọ́ òsi rẹ, ninu ogo rẹ. Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère: ẹnyin le mu ago ti emi mu? tabi ki a fi baptismu ti a fi baptisi mi baptisi nyin? Nwọn si wi fun u pe, Awa le ṣe e. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin ó mu ago ti emi mu; ati baptismu ti a o fi baptisi mi li a o fi baptisi nyin: Ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún mi ati li ọwọ́ òsi mi ki iṣe ti emi lati fi funni: bikoṣe fun awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ.
Kà Mak 10
Feti si Mak 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 10:32-40
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò