Mak 10:23-27

Mak 10:23-27 YBCV

Jesu si wò yiká, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun! Ẹnu si yà awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ọ̀rọ rẹ̀. Ṣugbọn Jesu si tun dahùn wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọ, yio ti ṣoro to fun awọn ti o gbẹkẹle ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun! O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ. Ẹnu si yà wọn rekọja, nwọn si mba ara wọn sọ wipe, Njẹ tali o ha le là? Jesu si wò wọn o wipe, Enia li eyi ko le ṣe iṣe fun, ṣugbọn ki iṣe fun Ọlọrun: nitori ohun gbogbo ni ṣiṣe fun Ọlọrun.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ