Mak 1:1-9

Mak 1:1-9 YBCV

IBẸRẸ ihinrere Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun. Bi a ti kọ ọ ninu iwe woli Isaiah: Kiyesi i, mo rán onṣẹ mi ṣiwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ. Ohùn ẹnikan ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ ṣe oju ọ̀na rẹ̀ tọ́. Johanu de, ẹniti o mbaptisi ni iju, ti o si nwasu baptismu ironupiwada fun idariji ẹ̀ṣẹ. Gbogbo ilẹ Judea, ati gbogbo awọn ará Jerusalemu jade tọ̀ ọ lọ, a si ti ọwọ́ rẹ̀ baptisi gbogbo wọn li odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn. Johanu si wọ̀ aṣọ irun ibakasiẹ, o si dì amure awọ mọ ẹgbẹ rẹ̀; o si njẹ ẽṣú ati oyin ìgan. O si nwasu, wipe, Ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, okùn bata ẹsẹ ẹniti emi ko to bẹ̀rẹ tú: Emi fi omi baptisi nyin; ṣugbọn on yio fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin. O si ṣe li ọjọ wọnni, Jesu jade wá lati Nasareti ti Galili, a si ti ọwọ́ Johanu baptisi rẹ̀ li odò Jordani.

Àwọn fídíò fún Mak 1:1-9