Mik 7:1-8

Mik 7:1-8 YBCV

EGBE ni fun mi! nitori emi dàbi ikojọpọ̀ eso ẹ̃rùn, bi ẽṣẹ́ ikorè eso àjara: kò si ití kan lati jẹ: akọso ti ọkàn mi fẹ. Oninurere ti run kuro li aiye: kò si si olotitọ kan ninu enia: gbogbo wọn ba fun ẹ̀jẹ, olukuluku wọn nfi àwọn dẹ arakunrin rẹ̀. Ọwọ́ wọn ti mura tan lati ṣe buburu, olori mbère, onidajọ si mbère fun ẹsan; ẹni-nla nsọ ìro ika rẹ̀, nwọn si nyi i po. Ẹniti o sànjulọ ninu wọn dàbi ẹ̀gun: ìduroṣiṣin julọ mú jù ẹgún ọgbà lọ: ọjọ awọn olùṣọ rẹ ati ti ìbẹwo rẹ de; nisisiyi ni idãmu wọn o de. Ẹ má gba ọrẹ́ kan gbọ́, ẹ má si gbẹkẹ̀le amọ̀na kan: pa ilẹkùn ẹnu rẹ mọ fun ẹniti o sùn ni õkan-àiya rẹ. Nitori ọmọkunrin nṣàibọ̀wọ fun baba, ọmọbinrin dide si ìya rẹ̀, aya-ọmọ si iyakọ rẹ̀; ọta olukuluku ni awọn ara ile rẹ̀. Nitorina emi o ni ireti si Oluwa: emi o duro de Ọlọrun igbala mi: Ọlọrun mi yio gbọ́ temi. Má yọ̀ mi, Iwọ ọta mi: nigbati mo ba ṣubu, emi o dide; nigbati mo ba joko li okùnkun, Oluwa yio jẹ imọlẹ fun mi.