Mik 6:4-5

Mik 6:4-5 YBCV

Nitori mo ti mu ọ goke lati ilẹ Egipti wá, mo si rà ọ padà lati ile ẹrú wá; mo si rán Mose, Aaroni, ati Miriamu siwaju rẹ. Enia mi, ranti nisisiyi ohun ti Balaki ọba Moabu gbèro, ati ohun ti Balaamu ọmọ Beori dá a lohùn lati Ṣittimu titi de Gilgali; ki ẹ ba le mọ̀ ododo Oluwa.