Mik 4:3-8

Mik 4:3-8 YBCV

On o si ṣe idajọ lãrin ọ̀pọlọpọ enia, yio si bá alagbara orilẹ-ède rére wi; nwọn o si fi idà wọn rọ ọbẹ irin-itulẹ̀, ati ọ̀kọ wọn rọ dojé: orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède, bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ. Ṣugbọn nwọn o joko olukuluku labẹ ajara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ̀; ẹnikan kì yio si daiyà fò wọn: nitori ẹnu Oluwa awọn ọmọ-ogun li o ti sọ ọ. Nitori gbogbo awọn enia ni yio ma rìn, olukuluku li orukọ ọlọrun tirẹ̀, awa o si ma rìn li orukọ Oluwa Ọlọrun wa lai ati lailai. Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o kó amukun, emi o si ṣà ẹniti a le jade, ati ẹniti emi ti pọn loju jọ; Emi o si dá awọn amukun si fun iyokù, emi o si sọ ẹniti a ta nù rére di orilẹ-ède alagbara: Oluwa yio si jọba lori wọn li oke-nla Sioni lati isisiyi lọ, ati si i lailai. Ati iwọ, Ile iṣọ agbo agùtan, odi ọmọbinrin Sioni, si ọdọ rẹ ni yio wá, ani ijọba iṣãju; ijọba yio si wá si ọdọ ọmọbinrin Jerusalemu.