Obinrin awọn enia mi li ẹnyin ti le jade kuro ninu ile wọn daradara; ẹnyin ti gbà ogo mi kuro lọwọ awọn ọmọ wọn lailai. Ẹ dide, ki ẹ si ma lọ; nitoripe eyi kì iṣe ibi isimi: nitoriti o jẹ alaimọ́, yio pa nyin run, ani iparun kikorò? Bi enia kan ti nrin ninu ẹmi ati itanjẹ ba ṣeke, wipe, emi o sọ asọtẹlẹ̀ ti ọti-waini ati ọti-lile fun ọ; on ni o tilẹ ṣe woli awọn enia yi. Ni kikó emi o kó nyin jọ, iwọ Jakobu, gbogbo nyin; ni gbigbá emi o gbá iyokù Israeli jọ; emi o si tò wọn jọ pọ̀ gẹgẹ bi agutan Bosra, gẹgẹ bi ọwọ́ ẹran ninu agbo wọn: nwọn o si pariwo nla nitori ọ̀pọlọpọ enia. Ẹniti nfọ́ni ti dide niwaju wọn: nwọn ti fọ́, nwọn kọja lãrin bode, nwọn si ti jade lọ nipa rẹ̀: ọba wọn o si kọja lọ niwaju wọn, Oluwa ni yio si ṣe olori wọn.
Kà Mik 2
Feti si Mik 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mik 2:9-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò