Mat 6:28-32

Mat 6:28-32 YBCV

Ẽṣe ti ẹnyin sì fi nṣe aniyan nitori aṣọ? Kiyesi lili ti mbẹ ni igbẹ́, bi nwọn ti ndàgba; nwọn kì iṣiṣẹ, bẹ̃ni nwọn kì irànwu: Mo si wi fun nyin pe, a ko ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ ninu gbogbo ogo rẹ̀ to bi ọkan ninu wọnyi. Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ bẹ̃, eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu iná lọla, melomelo ni ki yio fi le wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin oni-kekere igbagbọ? Nitorina ẹ maṣe ṣe aniyan, wipe, Kili a o jẹ? tabi, Kili a o mu? tabi, aṣọ wo li a o fi wọ̀ wa? Nitori gbogbo nkan wọnyi li awọn keferi nwá kiri. Nitori Baba nyin ti mbẹ li ọrun mọ̀ pe, ẹnyin kò le ṣe alaini gbogbo nkan wọnyi.

Àwọn fídíò fún Mat 6:28-32