Alabukún-fun li awọn òtoṣi li ẹmí: nitori tiwọn ni ijọba ọrun. Alabukún-fun li awọn ẹniti nkãnu: nitoriti a ó tù wọn ninu. Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye. Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo: nitori nwọn ó yo. Alabukún-fun li awọn alãnu: nitori nwọn ó ri ãnu gbà. Alabukún-fun li awọn oninu-funfun: nitori nwọn ó ri Ọlọrun. Alabukún-fun li awọn onilaja: nitori ọmọ Ọlọrun ni a ó ma pè wọn. Alabukúnfun li awọn ẹniti a ṣe inunibini si nitori ododo: nitori tiwọn ni ijọba ọrun. Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati nwọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba nfi eke sọ̀rọ buburu gbogbo si nyin nitori emi. Ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o si fò fun ayọ̀: nitori ère nyin pọ̀ li ọrun: bẹ̃ni nwọn sá ṣe inunibini si awọn wolĩ ti o ti mbẹ ṣaju nyin. Ẹnyin ni iyọ̀ aiye: ṣugbọn bi iyọ̀ ba di obu, kini a o fi mu u dùn? kò nilari mọ́, bikoṣepe a dà a nù, ki o si di itẹmọlẹ li atẹlẹsẹ enia. Ẹnyin ni imọlẹ aiye. Ilu ti a tẹ̀do lori òke ko le farasin. Bẹ̃ni a kì itàn fitila tan, ki a si fi i sabẹ òṣuwọn; bikoṣe lori ọpá fitila, a si fi imọlẹ fun gbogbo ẹniti mbẹ ninu ile. Ẹ jẹ ki imọlẹ nyin ki o mọlẹ tobẹ̃ niwaju enia, ki nwọn ki o le mã ri iṣẹ rere nyin, ki nwọn ki o le ma yìn Baba nyin ti mbẹ li ọrun logo.
Kà Mat 5
Feti si Mat 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 5:3-16
5 Days
‘Tis the season to be jolly, but also very busy. Come away for a few moments of rest and worship that will sustain you throughout the merry labors of the season. Based on the book Unwrapping the Names of Jesus: An Advent Devotional , this 5-day devotional reading plan will guide you to receive Jesus’ rest this Christmas by taking moments to remember His goodness, express your neediness, seek His stillness, and trust His faithfulness.
7 Days
Taken from Kyle Idleman's follow-up to "Not A Fan," you're invited to find the end of yourself, because only then can you embrace the inside-out ways of Jesus.
We’re all chasing something. Usually something just out of reach—a better job, a more comfortable home, a perfect family, the approval of others. But isn’t this tiring? Is there a better way? Find out in this new Life.Church Bible Plan, accompanying Pastor Craig Groeschel’s message series, Chasing Carrots.
8 Days
In the Beatitudes (Matthew 5:2–12), Jesus urges us to set ourselves apart from the world, living in a counterculture with a new identity rooted in him. The Upside Down Kingdom examines this counterintuitive wisdom and explores its relevance for today.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò