Mat 5:23-26

Mat 5:23-26 YBCV

Nitorina bi iwọ ba nmu ẹ̀bun rẹ wá si ibi pẹpẹ, bi iwọ ba si ranti nibẹ pe, arakunrin rẹ li ohun kan ninu si ọ, Fi ẹ̀bun rẹ silẹ nibẹ̀ niwaju pẹpẹ, si lọ, kọ́ ba arakunrin rẹ làja na, nigbana ni ki o to wá ibùn ẹ̀bun rẹ. Ba ọtà rẹ rẹ́ kánkan nigbati iwọ wà li ọ̀na pẹlu rẹ̀; ki ọtá rẹ ki o má ba fi ọ le onidajọ lọwọ, onidajọ a si fi ọ le ẹ̀ṣọ lọwọ, a si gbè ọ sọ sinu tubu. Lõtọ ni mo wi fun ọ, Iwọ kì yio jade kuro nibẹ̀, titi iwọ o fi san õkan ti o ba kù.

Àwọn fídíò fún Mat 5:23-26