Mat 4:1-4

Mat 4:1-4 YBCV

NIGBANA li a dari Jesu si ijù lati ọwọ́ Ẹmi lati dán a wò lọwọ Èṣu. Nigbati o si ti gbàwẹ li ogoji ọsán ati ogoji oru, lẹhinna ni ebi npa a. Nigbati oludanwò de ọdọ rẹ̀, o ni, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ ki okuta wọnyi di akara. Ṣugbọn o dahùn wipe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Enia kì yio wà lãyè nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade wá.

Àwọn fídíò fún Mat 4:1-4