Mat 27:51-56

Mat 27:51-56 YBCV

Si wo o, aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán; Awọn isà okú si ṣí silẹ; ọ̀pọ okú awọn ẹni mimọ́ ti o ti sùn si jinde, Nwọn ti inu isà okú wọn jade lẹhin ajinde rẹ̀, nwọn si wá si ilu mimọ́, nwọn si farahàn ọ̀pọlọpọ enia. Nigbati balogun ọrún, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, ti nwọn nṣọ́ Jesu, ri isẹlẹ na, ati ohun wọnni ti ó ṣẹ̀, èru ba wọn gidigidi, nwọn wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li eyi iṣe. Awọn obinrin pipọ, li o wà nibẹ̀, ti nwọn ńwòran lati òkẽrè, awọn ti o ba Jesu ti Galili wá, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u: Ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu ati Jose, ati iya awọn ọmọ Sebede.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ