Awọn ti nkọja lọ si nfi ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, Wipe, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, gbà ara rẹ là. Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, sọkalẹ lati ori agbelebu wá. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu awọn akọwe, ati awọn àgbãgba nfi ṣe ẹlẹya, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ara rẹ̀ ni kò le gbalà. Ọba Israeli sa ni iṣe, jẹ ki o sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, awa o si gbà a gbọ́. O gbẹkẹle Ọlọrun; jẹ ki o gbà a là nisisiyi, bi o ba fẹran rẹ̀: o sá wipe, Ọmọ Ọlọrun li emi. Awọn olè ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nfi eyi na gún u loju bakanna. Lati wakati kẹfa, ni òkunkun ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan. Niwọn wakati kẹsan ni Jesu si kigbe li ohùn rara wipe, Eli, Eli, lama sabaktani? eyini ni, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ?
Kà Mat 27
Feti si Mat 27
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 27:39-46
8 Days
The final week in the life of Jesus was no ordinary week. It was a time of bittersweet goodbyes, lavish giving, cruel betrayals and prayers that shook heaven. Experience this week, from Palm Sunday to the miraculous Resurrection, as we read through the Biblical account together. We will cheer with the crowds on Jerusalem’s streets, shout in anger at Judas and the Roman soldiers, cry with the women at the Cross, and celebrate as Easter morning dawns!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò