Mat 26:36-40

Mat 26:36-40 YBCV

Nigbana ni Jesu bá wọn wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi nigbati mo ba lọ igbadura lọhúnyi. O si mu Peteru ati awọn ọmọ Sebede mejeji pẹlu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ si banujẹ, o si bẹ̀rẹ si rẹ̀wẹ̀sì. Nigbana li o wi fun wọn pe, Ọkàn mi bajẹ gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihinyi, ki ẹ si mã ba mi sọ́na. O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yi ki o kọja kuro lori mi, ṣugbọn kì í ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ. O si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o bá wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Kinla, ẹnyin ko le bá mi ṣọ́na ni wakati kan?

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ