Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi.
Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Gbogbo nyin ni yio kọsẹ̀ lara mi li oru yi: nitoriti a ti kọwe rẹ̀ pe, Emi o kọlù oluṣọ-agutan, a o si tú agbo agutan na ká kiri.
Ṣugbọn lẹhin igba ti mo ba jinde, emi o ṣaju nyin lọ si Galili.
Peteru si dahùn o wi fun u pe, Bi gbogbo enia tilẹ kọsẹ̀ lara rẹ, emi kì yio kọsẹ̀ lai.
Jesu wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ pe, Li oru yi ki akukọ ki o to kọ iwọ o sẹ́ mi nigba mẹta.
Peteru wi fun u pe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi kò jẹ sẹ́ ọ. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo awọn ọmọ-ẹhin wi pẹlu.
Nigbana ni Jesu bá wọn wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi nigbati mo ba lọ igbadura lọhúnyi.
O si mu Peteru ati awọn ọmọ Sebede mejeji pẹlu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ si banujẹ, o si bẹ̀rẹ si rẹ̀wẹ̀sì.
Nigbana li o wi fun wọn pe, Ọkàn mi bajẹ gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihinyi, ki ẹ si mã ba mi sọ́na.
O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yi ki o kọja kuro lori mi, ṣugbọn kì í ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ.
O si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o bá wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Kinla, ẹnyin ko le bá mi ṣọ́na ni wakati kan?
Ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura, ki ẹnyin ki o má ba bọ sinu idẹwò: lõtọ li ẹmi nfẹ ṣugbọn o ṣe alailera fun ara.
O si tún pada lọ li ẹrinkeji, o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi ago yi kò ba le ré mi kọja bikoṣepe mo mu ú, ifẹ tirẹ ni ki a ṣe.
O si wá, o si tun bá wọn, nwọn nsùn: nitoriti oju wọn kun fun orun.
O si fi wọn silẹ, o si tún pada lọ o si gbadura li ẹrinkẹta, o nsọ ọ̀rọ kanna.
Nigbana li o tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã sùn wayi, ki ẹ si mã simi: wo o, wakati kù fẹfẹ, ti a o si fi Ọmọ-ẹnia le awọn ẹlẹṣẹ lọwọ.
Ẹ dide, ki a mã lọ: wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi.