Ṣugbọn lãrin ọganjọ, igbe ta soke, wipe, Wo o, ọkọ, iyawo mbọ̀; ẹ jade lọ ipade rẹ̀. Nigbana ni gbogbo awọn wundia wọnni dide, nwọn, si tún fitila wọn ṣe. Awọn alaigbọn si wi fun awọn ọlọgbọn pe, Fun wa ninu oróro nyin; nitori fitila wa nkú lọ. Ṣugbọn awọn ọlọ́gbọn da wọn li ohùn, wipe, Bẹ̃kọ; ki o má ba ṣe alaito fun awa ati ẹnyin: ẹ kuku tọ̀ awọn ti ntà lọ, ki ẹ si rà fun ara nyin. Nigbati nwọn si nlọ rà, ọkọ iyawo de; awọn ti o si mura tan bá a wọle lọ si ibi iyawo: a si tì ilẹkun.
Kà Mat 25
Feti si Mat 25
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 25:6-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò