Mat 25:37-40

Mat 25:37-40 YBCV

Nigbana li awọn olõtọ yio da a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li onjẹ? tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, ti awa fun ọ li ohun mimu? Nigbawo li awa ri ọ li alejò, ti a gbà ọ si ile? tabi ti iwọ wà ni ìhoho, ti awa daṣọ bò ọ? Tabi nigbawo li awa ri ti iwọ ṣe aisan, ti a bojuto ọ? tabi ti iwọ wà ninu tubu, ti awa si tọ̀ ọ wá? Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi.

Àwọn fídíò fún Mat 25:37-40