Lẹhin igba ti o pẹ titi, oluwa awọn ọmọ-ọdọ wọnni de, o ba wọn ṣiro. Eyi ti o gbà talenti marun si wá, o si mu talenti marun miran wá pẹlu, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti marun fun mi: si wò o, mo jère talenti marun miran. Oluwa rẹ̀ wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ: iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwo bọ́ sinu ayọ̀ Oluwa rẹ. Eyi ti o gbà talenti meji pẹlu si wá, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti meji fun mi: wo o, mo jère talenti meji miran. Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ; iwọ ṣe olõtọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.
Kà Mat 25
Feti si Mat 25
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 25:19-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò