Mat 24:9-14

Mat 24:9-14 YBCV

Nigbana ni nwọn o fi nyin funni lati jẹ ni ìya, nwọn o si pa nyin: a o si korira nyin lọdọ gbogbo orilẹ-ède nitori orukọ mi. Nigbana li ọ̀pọlọpọ yio kọsẹ̀, nwọn o si ma ṣòfofo ara wọn, nwọn o si mã korira ara wọn. Wolĩ eke pipọ ni yio si dide, nwọn o si tàn ọpọlọpọ jẹ. Ati nitori ẹ̀ṣẹ yio di pipọ, ifẹ ọpọlọpọ yio di tutù. Ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi de opin, on na li a o gbalà. A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de.

Àwọn fídíò fún Mat 24:9-14