Mat 24:37-44

Mat 24:37-44 YBCV

Gẹgẹ bi ọjọ Noa si ti ri, bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio si ri. Nitori bi ọjọ wọnni ti wà ṣiwaju kikún omi, ti nwọn njẹ, ti nwọn nmu, ti nwọn ngbé iyawo, ti a si nfa iyawo funni, titi o fi di ọjọ ti Noa fi bọ́ sinu ọkọ̀, Nwọn kò si mọ̀ titi omi fi de, ti o gbá gbogbo wọn lọ; gẹgẹ bẹ̃ni wíwa Ọmọ-enia yio ri pẹlu. Nigbana li ẹni meji yio wà li oko; a o mu ọkan, a o si fi èkejì silẹ. Awọn obinrin meji yio jùmọ ma lọ̀ ọlọ pọ̀; a o mu ọkan, a o si fi ekeji silẹ. Nitorina ẹ mã ṣọna: nitori ẹnyin kò mọ̀ wakati ti Oluwa nyin yio de. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o mọ̀ eyi pe, bãle ile iba mọ̀ wakati na ti olè yio wá, iba ma ṣọna, on kì ba ti jẹ́ ki a runlẹ ile rẹ̀. Nitorina ki ẹnyin ki o mura silẹ: nitori ni wakati ti ẹnyin kò rò tẹlẹ li Ọmọ-enia yio de.

Àwọn fídíò fún Mat 24:37-44