Mat 24:33-36

Mat 24:33-36 YBCV

Gẹgẹ bẹ̃ li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri gbogbo nkan wọnyi, ki ẹ mọ̀ pe o sunmọ etile tan lẹhin ilẹkun. Lõtọ ni mo wi fun nyin, iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ. Ọrun on aiye yio rekọjá, ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja. Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ̀ ọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo.

Àwọn fídíò fún Mat 24:33-36