Mat 22:17-21

Mat 22:17-21 YBCV

Njẹ wi fun wa, Iwọ ti rò o si? Ó tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi ko tọ́? Ṣugbọn Jesu mọ̀ ìro buburu wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò, ẹnyin agabagebe? Ẹ fi owodẹ kan hàn mi. Nwọn si mu owo idẹ kan tọ̀ ọ wá. O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi? Nwọn wi fun u pe, Ti Kesari ni. Nigbana li o wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.

Àwọn fídíò fún Mat 22:17-21