Mat 21:8-13

Mat 21:8-13 YBCV

Ọ̀pọ ijọ enia tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na; ẹlomiran ṣẹ́ ẹka igi wẹ́wẹ́, nwọn si fún wọn si ọ̀na. Ijọ enia ti nlọ niwaju, ati eyi ti ntọ̀ wọn lẹhin, nkigbe wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa; Hosanna loke ọrun. Nigbati o de Jerusalemu, gbogbo ilu mì titi, wipe, Tani yi? Ijọ enia si wipe, Eyi ni Jesu wolĩ, lati Nasareti ti Galili. Jesu si wọ̀ inu tẹmpili Ọlọrun lọ, o si lé gbogbo awọn ẹniti ntà, ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si yi tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle. O si wi fun wọn pe, A ti kọ ọ pe, Ile adura li a ó ma pè ile mi; ṣugbọn ẹnyin sọ ọ di ihò ọlọṣà.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ