Ṣugbọn kili ẹnyin nrò? Ọkunrin kan wà ti o li ọmọ ọkunrin meji; o tọ̀ ekini wá, o si wipe, Ọmọ, lọ iṣiṣẹ loni ninu ọgba ajara mi. O si dahùn wipe, Emi kì yio lọ: ṣugbọn o ronu nikẹhin, o si lọ. O si tọ̀ ekeji wá, o si wi bẹ̃ gẹgẹ. O si dahùn wi fun u pe, Emi o lọ, baba: kò si lọ. Ninu awọn mejeji, ewo li o ṣe ifẹ baba rẹ̀? Nwọn wi fun u pe, Eyi ekini. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, awọn agbowode ati awọn panṣaga ṣiwaju nyin lọ si ijọba Ọlọrun. Nitori Johanu ba ọ̀na ododo tọ̀ nyin wá, ẹnyin kò si gbà a gbọ́: ṣugbọn awọn agbowode ati awọn panṣaga gbà a gbọ́: ṣugbọn ẹnyin, nigbati ẹnyin si ri i, ẹ kò ronupiwada nikẹhin, ki ẹ le gbà a gbọ́.
Kà Mat 21
Feti si Mat 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 21:28-32
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò