Mat 20:17-28

Mat 20:17-28 YBCV

Jesu si ngoke lọ si Jerusalemu, o si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejila si apakan li ọ̀na, o si wi fun wọn pe, Wò o, awa ngoke lọ si Jerusalemu; a o si fi Ọmọ-enia le awọn olori alufa, ati awọn akọwe lọwọ, nwọn o si da a lẹbi ikú. Nwọn o si fà a le awọn keferi lọwọ lati fi i ṣe ẹlẹyà, lati nà a, ati lati kàn a mọ agbelebu: ni ijọ kẹta yio si jinde. Nigbana ni iya awọn ọmọ Sebede ba awọn ọmọ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o bẹ̀ ẹ, o si nfẹ ohun kan li ọwọ́ rẹ̀. O si bi i pe, Kini iwọ nfẹ? O wi fun u pe, Jẹ ki awọn ọmọ mi mejeji ki o mã joko, ọkan li ọwọ́ ọtún rẹ, ọkan li ọwọ́ òsi ni ijọba rẹ. Ṣugbọn Jesu dahùn, o si wipe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère. Ẹnyin le mu ninu ago ti emi ó mu, ati ki a fi baptismu ti a o fi baptisi mi baptisi nyin? Nwọn wi fun u pe, Awa le ṣe e. O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o mu ninu ago mi, ati ninu baptismu ti a o fi baptisi mi li a o si fi baptisi nyin; ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún ati li ọwọ́ òsi mi, ki iṣe ti emi lati fi funni, bikoṣepe fun kìki awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ fun lati ọdọ Baba mi wá. Nigbati awọn mẹwa iyokù gbọ́ ọ, nwọn binu si awọn arakunrin wọn mejeji. Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹnyin mọ̀ pe awọn ọba Keferi a ma lò agbara lori wọn, ati awọn ẹni-nla ninu wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba. Ṣugbọn kì yio ri bẹ̃ lãrin nyin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ pọ̀ ninu nyin, ẹ jẹ ki o ṣe iranṣẹ nyin; Ati ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe olori ninu nyin, jẹ ki o ma ṣe ọmọ-ọdọ nyin: Ani gẹgẹ bi Ọmọ-enia kò ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia.

Àwọn fídíò fún Mat 20:17-28