Mat 2:13-18

Mat 2:13-18 YBCV

Nigbati nwọn si ti lọ, kiyesi i, angẹli Oluwa yọ si Josefu li oju alá, o wipe, Dide gbé ọmọ-ọwọ na pẹlu iya rẹ̀, ki o si sálọ si Egipti, ki iwọ ki o si gbé ibẹ̀ titi emi o fi sọ fun ọ; nitori Herodu yio wá ọmọ-ọwọ na lati pa a. Nigbati o si dide, o mu ọmọ-ọwọ na ati iya rẹ̀ li oru, o si lọ si Egipti; O si wà nibẹ̀ titi o fi di igba ikú Herodu; ki eyi ti Oluwa wi lati ẹnu woli nì ki o le ṣẹ, pe, Ni Egipti ni mo ti pè ọmọ mi jade wá. Nigbati Herodu ri pe, on di ẹni itanjẹ lọdọ awọn amoye, o binu gidigidi, o si ranṣẹ, o si pa gbogbo awọn ọmọ ti o wà ni Betlehemu ati ni ẹkùn rẹ̀, lati awọn ọmọ ọdún meji jalẹ gẹgẹ bi akokò ti o ti bere lẹsọlẹsọ lọwọ awọn amoye na. Nigbana li eyi ti a ti sọ lati ẹnu woli Jeremiah wa ṣẹ, pe, Ni Rama ni a gbọ́ ohùn, ohùnréré, ati ẹkún, ati ọ̀fọ nla, Rakeli nsọkun awọn ọmọ rẹ̀ ko gbipẹ, nitoriti nwọn ko si.

Àwọn fídíò fún Mat 2:13-18