Mat 18:23-27

Mat 18:23-27 YBCV

Nitorina ni ijọba ọrun fi dabi ọba kan ti nfẹ gbà ìṣirò lọwọ awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀. Nigbati o bẹ̀rẹ si gbà iṣiro, a mu ọkan tọ̀ ọ wá, ti o jẹ ẹ li ẹgbãrun talenti. Njẹ bi ko ti ni ohun ti yio fi san a, oluwa rẹ̀ paṣẹ pe ki a tà a, ati obinrin rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni, ki a si san gbese na. Nitorina li ọmọ-ọdọ na wolẹ o si tẹriba fun u, o nwipe, Oluwa, mu sũru fun mi, emi ó si san gbogbo rẹ̀ fun ọ. Oluwa ọmọ-ọdọ na si ṣãnu fun u, o tú u silẹ, o fi gbese na jì i.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ