Mat 18:15-22

Mat 18:15-22 YBCV

Pẹlupẹlu bi arakunrin rẹ ba sẹ̀ ọ, lọ sọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ fun u ti iwọ tirẹ̀ meji: bi o ba gbọ́ tirẹ, iwọ mu arakunrin rẹ bọ̀ sipò. Ṣugbọn bi kò ba gbọ́ tirẹ, nigbana ni ki iwọ ki o mu ẹnikan tabi meji pẹlu ara rẹ, ki gbogbo ọ̀rọ li ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta ba le fi idi mulẹ. Bi o ba si kọ̀ lati gbọ́ wọn, wi fun ijọ enia Ọlọrun: bi o ba si kọ̀ lati gbọ́ ti ijọ enia Ọlọrun, jẹ ki o dabi keferi si ọ ati agbowodè. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba dè li aiye, a o dè e li ọrun, ohunkohun ti ẹnyin ba si tú li aiye, a o tú u li ọrun. Mo wi fun nyin ẹ̀wẹ pe, Bi ẹni meji ninu nyin ba fi ohùn ṣọkan li aiye yi niti ohunkohun ti nwọn o bère; a o ṣe e fun wọn lati ọdọ Baba mi ti mbẹ li ọrun wá. Nitori nibiti ẹni meji tabi mẹta ba kó ara wọn jọ li orukọ mi, nibẹ̀ li emi o wà li ãrin wọn. Nigbana ni Peteru tọ̀ ọ wá, o wipe, Oluwa, nigba melo li arakunrin mi yio ṣẹ̀ mi, ti emi o si fijì i? titi di igba meje? Jesu wi fun u pe, Emi kò wi fun ọ pe, Titi di igba meje, bikoṣe Titi di igba ãdọrin meje.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ