LAKOKÒ na li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn bi i pe, Tali ẹniti o pọ̀ju ni ijọba ọrun?
Jesu si pe ọmọ kekere kan sọdọ rẹ̀, o mu u duro larin wọn,
O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin kì yio le wọle ijọba ọrun.
Nitorina ẹnikẹni ti o ba rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ bi ọmọ kekere yi, on na ni yio pọ̀ju ni ijọba ọrun.
Ẹniti o ba si gbà irú ọmọ kekere yi kan, li orukọ mi, o gbà mi,
Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o ya fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si rì i si ibú omi okun.
Egbé ni fun aiye nitori ohun ikọsẹ̀! ohun ikọsẹ̀ ko le ṣe ki o ma de; ṣugbọn egbé ni fun oluwarẹ̀ na nipasẹ ẹniti ohun ikọsẹ̀ na ti wá!
Bi ọwọ́ rẹ tabi ẹsẹ rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro, ki o si sọ ọ nù; o sàn fun ọ ki o ṣe akewọ, tabí akesẹ lọ sinu ìye, jù ki o li ọwọ́ meji tabi ẹsẹ meji, ki a gbé ọ jù sinu iná ainipẹkun.
Bi oju rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade, ki o si sọ ọ nù; o sàn fun ọ ki o lọ sinu ìye li olojukan, jù ki o li oju meji, ki a gbé ọ sọ sinu iná ọrun apãdi.
Kiyesara ki ẹnyin má gàn ọkan ninu awọn kekeke wọnyi; nitori mo wi fun nyin pe, nigbagbogbo li ọrun li awọn angẹli wọn nwò oju Baba mi ti mbẹ li ọrun.
Nitori Ọmọ-enia wá lati gbà awọn ti o ti nù là.
Ẹnyin ti rò o si? bi ọkunrin kan ba ni ọgọrun agutan, bi ọkan nù ninu wọn, kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ̀, kì yio lọ sori òke lọ iwá eyi ti o nù bi?
Njẹ bi o ba si ri i lõtọ ni mo wi fun nyin, o yọ̀ nitori agutan na yi, jù mọkandilọgọrun iyokù lọ ti ko nù.
Gẹgẹ bẹ̃ni kì iṣe ifẹ Baba nyin ti mbẹ li ọrun, ki ọkan ninu awọn kekeke wọnyi ki o ṣegbé.
Pẹlupẹlu bi arakunrin rẹ ba sẹ̀ ọ, lọ sọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ fun u ti iwọ tirẹ̀ meji: bi o ba gbọ́ tirẹ, iwọ mu arakunrin rẹ bọ̀ sipò.
Ṣugbọn bi kò ba gbọ́ tirẹ, nigbana ni ki iwọ ki o mu ẹnikan tabi meji pẹlu ara rẹ, ki gbogbo ọ̀rọ li ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta ba le fi idi mulẹ.
Bi o ba si kọ̀ lati gbọ́ wọn, wi fun ijọ enia Ọlọrun: bi o ba si kọ̀ lati gbọ́ ti ijọ enia Ọlọrun, jẹ ki o dabi keferi si ọ ati agbowodè.
Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba dè li aiye, a o dè e li ọrun, ohunkohun ti ẹnyin ba si tú li aiye, a o tú u li ọrun.
Mo wi fun nyin ẹ̀wẹ pe, Bi ẹni meji ninu nyin ba fi ohùn ṣọkan li aiye yi niti ohunkohun ti nwọn o bère; a o ṣe e fun wọn lati ọdọ Baba mi ti mbẹ li ọrun wá.
Nitori nibiti ẹni meji tabi mẹta ba kó ara wọn jọ li orukọ mi, nibẹ̀ li emi o wà li ãrin wọn.
Nigbana ni Peteru tọ̀ ọ wá, o wipe, Oluwa, nigba melo li arakunrin mi yio ṣẹ̀ mi, ti emi o si fijì i? titi di igba meje?
Jesu wi fun u pe, Emi kò wi fun ọ pe, Titi di igba meje, bikoṣe Titi di igba ãdọrin meje.