Mat 17:19-23

Mat 17:19-23 YBCV

Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá lẹhin, nwọn bi i pe, Ẽṣe ti awa kò fi le lé e jade? Jesu si wi fun wọn pe, Nitori aigbagbọ́ nyin ni: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irúgbin mustardi, ẹnyin o wi fun òke yi pe, Ṣi nihin lọ si ọ̀hun, yio si ṣi; kò si si nkan ti ẹ ki yio le ṣe. Ṣugbọn irú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwẹ̀. Nigbati nwọn mbẹ ni Galili, Jesu wi fun wọn pe, A o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ: Nwọn o si pa a, ni ijọ kẹta yio si jinde. Inu wọn si bajẹ gidigidi.

Àwọn fídíò fún Mat 17:19-23