Mat 17:14-18

Mat 17:14-18 YBCV

Nigbati nwọn si de ọdọ ijọ enia, ọkunrin kan si tọ ọ wá, o kunlẹ fun u, o si wipe, Oluwa, ṣãnu ọmọ mi, nitori o ni warapa, o si njoro gidigidi: nigba pupọ ni ima ṣubu sinu iná, ati nigba pupọ sinu omi. Mo si mu u tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ wá, nwọn kò si le mu u larada. Jesu si dahùn, o wipe, A! iran alaigbàgbọ́ ati arekereke yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? Gbé ọmọ na tọ̀ mi wá nihin. Jesu si ba a wi, ẹmi èṣu na si jade kuro lara rẹ̀; a si mu ọmọ na larada ni wakati kanna.

Àwọn fídíò fún Mat 17:14-18