Mat 13:47-52

Mat 13:47-52 YBCV

Ati pẹlu, ijọba ọrun si dabi àwọn, ti a sọ sinu okun, ti o si kó onirũru ohun gbogbo. Nigbati o kún, eyi ti nwọn fà soke, nwọn joko, nwọn si kó eyi ti o dara sinu agbọ̀n, ṣugbọn nwọn kó buburu danù. Gẹgẹ bẹ̃ni yio si ri nigbẹhin aiye: awọn angẹli yio jade wá, nwọn o yà awọn enia buburu kuro ninu awọn olõtọ, Nwọn o si sọ wọn sinu iná ileru; nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà. Jesu bi wọn pe, Gbogbo nkan wọnyi yé nyin bi? Nwọn wi fun u pe, Bẹ̃ni, Oluwa. O si wi fun wọn pe, Nitorina ni olukuluku akọwe ti a kọ́ sipa ijọba ọrun ṣe dabi ọkunrin kan ti iṣe bãle, ti o nmu ọtun ati ogbó nkan jade ninu iṣura rẹ̀.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ