Mat 13:33-35

Mat 13:33-35 YBCV

Owe miran li o pa fun wọn pe, Ijọba ọrun dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o sin sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ fi di wiwu. Gbogbo nkan wọnyi ni Jesu fi powe fun awọn ijọ enia; kò si ba wọn sọ̀rọ bikoṣe li owe: Ki eyiti a ti ẹnu woli sọ ki o ba le ṣẹ, wipe, Emi ó yà ẹnu mi li owe; emi ó sọ nkan wọnni jade ti o ti fi ara pamọ́ lati iṣẹ̀dalẹ aiye wá.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ