Mat 13:19-23

Mat 13:19-23 YBCV

Nigbati ẹnikan ba gbọ́ ọ̀rọ ijọba, ti kò ba si yé e, nigbana li ẹni-buburu ni wá, a si mu eyi ti a fún si àiya rẹ̀ kuro. Eyi li ẹniti o gbà irugbin lẹba ọ̀na. Ẹniti o si gbà irugbin lori apata, on li o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si fi ayọ̀ gbà a kánkan. Ṣugbọn ko ni gbongbo ninu ara rẹ̀, o si pẹ diẹ li akokò kan; nigbati wahalà tabi inunibini si dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna a kọsẹ̀. Eyi pẹlu ti o gbà irugbin sarin ẹgún li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na; aniyan aiye yi, ati itanjẹ ọrọ̀ si fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso. Ṣugbọn ẹniti o gbà irugbin si ilẹ rere li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si yé e; on li o si so eso pẹlu, o si so omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ