Mat 11:11-15

Mat 11:11-15 YBCV

Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ninu awọn ti a bí ninu obinrin, kò si ẹniti o ti idide jù Johanu Baptisti lọ; ṣugbọn ẹniti o kere julọ ni ijọba ọrun o pọ̀ ju u lọ. Lati igba ọjọ Johanu Baptisti wá, titi o fi di isisiyi ni ijọba ọrun di ifi agbara wọ, awọn alagbara si fi ipá gbà a. Nitori gbogbo awọn wolĩ ati ofin li o wi tẹlẹ ki Johanu ki o to de. Bi ẹnyin o ba gbà a, eyi ni Elijah ti mbọ̀ wá. Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.

Àwọn fídíò fún Mat 11:11-15