Mat 10:21-23

Mat 10:21-23 YBCV

Arakunrin yio si fi arakunrin rẹ̀ fun pipa, ati baba yio si fi ọmọ rẹ̀ fun pipa: awọn ọmọ yio si dide si awọn obi wọn nwọn o si mu ki a pa wọn. Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà. Ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣe inunibini si nyin ni ilu yi, ẹ sá lọ si omiran: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ẹnyin kì ó le rekọja gbogbo ilu Israeli tan titi Ọmọ enia ó fi de.

Àwọn fídíò fún Mat 10:21-23