Mat 10:16-33

Mat 10:16-33 YBCV

Wo o, mo rán nyin lọ gẹgẹ bi agutan sãrin ikõkò; nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n bi ejò, ki ẹ si ṣe oniwà tutù bi àdaba. Ṣugbọn ẹ ṣọra lọdọ enia; nitori nwọn o fi nyin le ajọ igbimọ lọwọ, nwọn o si nà nyin ninu sinagogu wọn. A o si mu nyin lọ siwaju awọn bãlẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn ati si awọn keferi. Nigbati nwọn ba si fi nyin le wọn lọwọ, ẹ máṣe ṣàniyan pe, bawo tabi kili ẹnyin o wi? nitoriti a o fi ohun ti ẹnyin o wi fun nyin ni wakati kanna. Nitoripe ki iṣe ẹnyin li o nsọ, ṣugbọn Ẹmí Baba nyin ni nsọ ninu nyin. Arakunrin yio si fi arakunrin rẹ̀ fun pipa, ati baba yio si fi ọmọ rẹ̀ fun pipa: awọn ọmọ yio si dide si awọn obi wọn nwọn o si mu ki a pa wọn. Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà. Ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣe inunibini si nyin ni ilu yi, ẹ sá lọ si omiran: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ẹnyin kì ó le rekọja gbogbo ilu Israeli tan titi Ọmọ enia ó fi de. Ọmọ-ẹhin kì ijù olukọ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni ọmọ-ọdọ ẹni ki ijù oluwa rẹ̀ lọ. O to fun ọmọ-ẹhin ki o dabi olukọ rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ ki o dabi oluwa rẹ̀. Bi nwọn ba pè bãle ile ni Beelsebubu, melomelo ni awọn ara ile rẹ̀? Nitorina ẹ má fòiya wọn; nitoriti ko si ohun ti a bò, ti ki o farahàn; ati eyi ti o farasin, ti a ki yio mọ̀. Ohun ti mo ba wi fun nyin li òkunkun, on ni ki ẹnyin ki o sọ ni imọlẹ; ati eyi ti ẹnyin gbọ́ si etí ni ki ẹ kede rẹ̀ lori ile. Ẹ má fòiya awọn ẹniti ipa ara, ṣugbọn ti nwọn ko le pa ọkàn: ṣugbọn ẹ kuku fòiya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi. Ologoṣẹ meji ki a ntà ni owo idẹ kekere kan? bẹ̃ni ko si ọkan ninu wọn ti yio ṣubu silẹ lẹhin Baba nyin. Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan. Nitorina ẹ má fòiya; ẹnyin ni iye lori jù ọ̀pọ ologoṣẹ lọ. Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, on li emi o jẹwọ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun. Ṣugbọn bi ẹnikan ba si sẹ mi niwaju enia, on na li emi o sẹ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.

Àwọn fídíò fún Mat 10:16-33

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún Mat 10:16-33

Mat 10:16-33 - Wo o, mo rán nyin lọ gẹgẹ bi agutan sãrin ikõkò; nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n bi ejò, ki ẹ si ṣe oniwà tutù bi àdaba.
Ṣugbọn ẹ ṣọra lọdọ enia; nitori nwọn o fi nyin le ajọ igbimọ lọwọ, nwọn o si nà nyin ninu sinagogu wọn.
A o si mu nyin lọ siwaju awọn bãlẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn ati si awọn keferi.
Nigbati nwọn ba si fi nyin le wọn lọwọ, ẹ máṣe ṣàniyan pe, bawo tabi kili ẹnyin o wi? nitoriti a o fi ohun ti ẹnyin o wi fun nyin ni wakati kanna.
Nitoripe ki iṣe ẹnyin li o nsọ, ṣugbọn Ẹmí Baba nyin ni nsọ ninu nyin.
Arakunrin yio si fi arakunrin rẹ̀ fun pipa, ati baba yio si fi ọmọ rẹ̀ fun pipa: awọn ọmọ yio si dide si awọn obi wọn nwọn o si mu ki a pa wọn.
Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà.
Ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣe inunibini si nyin ni ilu yi, ẹ sá lọ si omiran: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ẹnyin kì ó le rekọja gbogbo ilu Israeli tan titi Ọmọ enia ó fi de.
Ọmọ-ẹhin kì ijù olukọ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni ọmọ-ọdọ ẹni ki ijù oluwa rẹ̀ lọ.
O to fun ọmọ-ẹhin ki o dabi olukọ rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ ki o dabi oluwa rẹ̀. Bi nwọn ba pè bãle ile ni Beelsebubu, melomelo ni awọn ara ile rẹ̀?

Nitorina ẹ má fòiya wọn; nitoriti ko si ohun ti a bò, ti ki o farahàn; ati eyi ti o farasin, ti a ki yio mọ̀.
Ohun ti mo ba wi fun nyin li òkunkun, on ni ki ẹnyin ki o sọ ni imọlẹ; ati eyi ti ẹnyin gbọ́ si etí ni ki ẹ kede rẹ̀ lori ile.
Ẹ má fòiya awọn ẹniti ipa ara, ṣugbọn ti nwọn ko le pa ọkàn: ṣugbọn ẹ kuku fòiya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi.
Ologoṣẹ meji ki a ntà ni owo idẹ kekere kan? bẹ̃ni ko si ọkan ninu wọn ti yio ṣubu silẹ lẹhin Baba nyin.
Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan.
Nitorina ẹ má fòiya; ẹnyin ni iye lori jù ọ̀pọ ologoṣẹ lọ.

Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, on li emi o jẹwọ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.
Ṣugbọn bi ẹnikan ba si sẹ mi niwaju enia, on na li emi o sẹ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.Mat 10:16-33 - Wo o, mo rán nyin lọ gẹgẹ bi agutan sãrin ikõkò; nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n bi ejò, ki ẹ si ṣe oniwà tutù bi àdaba.
Ṣugbọn ẹ ṣọra lọdọ enia; nitori nwọn o fi nyin le ajọ igbimọ lọwọ, nwọn o si nà nyin ninu sinagogu wọn.
A o si mu nyin lọ siwaju awọn bãlẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn ati si awọn keferi.
Nigbati nwọn ba si fi nyin le wọn lọwọ, ẹ máṣe ṣàniyan pe, bawo tabi kili ẹnyin o wi? nitoriti a o fi ohun ti ẹnyin o wi fun nyin ni wakati kanna.
Nitoripe ki iṣe ẹnyin li o nsọ, ṣugbọn Ẹmí Baba nyin ni nsọ ninu nyin.
Arakunrin yio si fi arakunrin rẹ̀ fun pipa, ati baba yio si fi ọmọ rẹ̀ fun pipa: awọn ọmọ yio si dide si awọn obi wọn nwọn o si mu ki a pa wọn.
Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà.
Ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣe inunibini si nyin ni ilu yi, ẹ sá lọ si omiran: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ẹnyin kì ó le rekọja gbogbo ilu Israeli tan titi Ọmọ enia ó fi de.
Ọmọ-ẹhin kì ijù olukọ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni ọmọ-ọdọ ẹni ki ijù oluwa rẹ̀ lọ.
O to fun ọmọ-ẹhin ki o dabi olukọ rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ ki o dabi oluwa rẹ̀. Bi nwọn ba pè bãle ile ni Beelsebubu, melomelo ni awọn ara ile rẹ̀?

Nitorina ẹ má fòiya wọn; nitoriti ko si ohun ti a bò, ti ki o farahàn; ati eyi ti o farasin, ti a ki yio mọ̀.
Ohun ti mo ba wi fun nyin li òkunkun, on ni ki ẹnyin ki o sọ ni imọlẹ; ati eyi ti ẹnyin gbọ́ si etí ni ki ẹ kede rẹ̀ lori ile.
Ẹ má fòiya awọn ẹniti ipa ara, ṣugbọn ti nwọn ko le pa ọkàn: ṣugbọn ẹ kuku fòiya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi.
Ologoṣẹ meji ki a ntà ni owo idẹ kekere kan? bẹ̃ni ko si ọkan ninu wọn ti yio ṣubu silẹ lẹhin Baba nyin.
Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan.
Nitorina ẹ má fòiya; ẹnyin ni iye lori jù ọ̀pọ ologoṣẹ lọ.

Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, on li emi o jẹwọ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.
Ṣugbọn bi ẹnikan ba si sẹ mi niwaju enia, on na li emi o sẹ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.