NIGBATI o si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejejila si ọdọ, o fi agbara fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́, lati ma lé wọn jade ati lati ṣe iwòsan gbogbo àrun ati gbogbo aisan.
Orukọ awọn aposteli mejila na ni wọnyi: Eyi ekini ni Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀;
Filippi, ati Bartolomeu; Tomasi, ati Matiu ti iṣe agbowode; Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Lebbeu, ẹniti a si npè ni Taddeu;
Simoni ara Kana, ati Judasi Iskariotu, ẹniti o fi i hàn.
Awọn mejejila wọnyi ni Jesu rán lọ, o si paṣẹ fun wọn pe, Ẹ máṣe lọ si ọ̀na awọn keferi, ẹ má si ṣe wọ̀ ilu awọn ará Samaria;
Ṣugbọn ẹ kuku tọ̀ awọn agutan ile Israeli ti o nù lọ.
Bi ẹnyin ti nlọ, ẹ mã wasu, wipe, Ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ.
Ẹ mã ṣe dida ara fun awọn olokunrùn, ẹ sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, ẹ si jí awọn okú dide, ki ẹ si mã lé awọn ẹmi èṣu jade: ọfẹ li ẹnyin gbà, ọfẹ ni ki ẹ fi funni.
Ẹ máṣe pèse wura, tabi fadaka, tabi idẹ sinu aṣuwọn nyin;
Tabi àpo fun àjo nyin, ki ẹ máṣe mu ẹwu meji, tabi bata, tabi ọpá; onjẹ oniṣẹ yẹ fun u.
Ilu-kilu tabi iletò-kileto ti ẹnyin ba wọ̀, ẹ wá ẹniti o ba yẹ nibẹ ri, nibẹ̀ ni ki ẹ si gbé titi ẹnyin o fi kuro nibẹ̀.
Nigbati ẹnyin ba si wọ̀ ile kan, ẹ kí i.
Bi ile na ba si yẹ, ki alafia nyin ki o bà sori rẹ̀; ṣugbọn bi ko ba yẹ, ki alafia nyin ki o pada sọdọ nyin.
Ẹnikẹni ti kò ba si gbà nyin, ti kò si gbọ́ ọ̀rọ nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro ni ile na tabi ni ilu na, ẹ gbọ̀n ekuru ẹsẹ nyin silẹ.
Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio san fun ilẹ Sodomu ati Gomorra li ọjọ idajọ jù fun ilu na lọ.