Mal 2:15-16

Mal 2:15-16 YBCV

On kò ha ti ṣe ọkan? bẹ̃li on ni iyokù ẹmi. Ẽ si ti ṣe jẹ ọkan? ki on ba le wá iru-ọmọ bi ti Ọlọrun. Nitorina ẹ tọju ẹmi nyin, ẹ má si jẹ ki ẹnikẹni hùwa ẹ̀tan si aya ewe rẹ̀. Nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli wipe, on korira ikọ̀silẹ: ẹnikan fi ìwa-ipá bò aṣọ rẹ̀ mọlẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitorina ẹ ṣọ ẹmi nyin, ki ẹ má ṣe hùwa ẹ̀tan.