Luk 9:51-56

Luk 9:51-56 YBCV

O si ṣe, nigbati ọjọ atigbà soke rẹ̀ pé, o gbé oju le gangan lati lọ si Jerusalemu. O si rán awọn onṣẹ lọ si iwaju rẹ̀: nigbati nwọn si lọ nwọn wọ̀ iletò kan ti iṣe ti ara Samaria lọ ipèse silẹ dè e. Nwọn kò si gbà a, nitoriti oju rẹ̀ dabi ẹnipe o nlọ si Jerusalemu. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ Jakọbu on Johanu si ri i, nwọn ni, Oluwa, iwọ ko jẹ ki awa ki o pè iná lati ọrun wá, ki a sun wọn lúlu, bi Elijah ti ṣe? Ṣugbọn Jesu yipada, o si ba wọn wi, o ni, Ẹnyin kò mọ̀ irú ẹmí ti mbẹ ninu nyin. Nitori Ọmọ-enia ko wá lati pa ẹmi enia run, bikoṣe lati gbà a là. Nwọn si lọ si iletò miran.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ