Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Kili a le mọ̀ owe yi si? O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ọ̀rọ ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn miran li owe; pe ni riri, ki nwọn ki o má le ri, ati ni gbigbọ ki o má le yé wọn. Njẹ owe na li eyi: Irugbin li ọ̀rọ Ọlọrun. Awọn ti ẹba ọ̀na li awọn ti o gbọ́; nigbana li Èṣu wá o si mu ọ̀rọ na kuro li ọkàn wọn, ki nwọn ki o má ba gbagbọ́, ki a ma ṣe gbà wọn là. Awọn ti ori apata li awọn, nigbati nwọn gbọ́, nwọn fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ na; awọn wọnyi kò si ni gbòngbo, nwọn a gbagbọ fun sã diẹ; nigba idanwò, nwọn a pada sẹhin. Awọn ti o bọ sinu ẹgún li awọn, nigbati nwọn gbọ́ tan, nwọn lọ, nwọn a si fi itọju ati ọrọ̀ ati irọra aiye fun u pa, nwọn kò si le so eso asogbo. Ṣugbọn ti ilẹ rere li awọn, ti nwọn fi ọkàn otitọ ati rere gbọ ọrọ na, nwọn di i mu ṣinṣin, nwọn si fi sũru so eso.
Kà Luk 8
Feti si Luk 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 8:9-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò