Luk 8:4-8

Luk 8:4-8 YBCV

Nigbati ọ̀pọ ijọ enia pejọ pọ̀, lati ilu gbogbo si tọ̀ ọ wá, o fi owe ba wọn sọ̀rọ pe: Afunrugbin kan jade lọ lati fun irugbin rẹ̀: bi o si ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na; a si tẹ̀ ẹ mọlẹ, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ṣà a jẹ. Omiran si bọ́ sori apata; bi o si ti hù jade, o gbẹ nitoriti kò ni irinlẹ omi. Omiran si bọ́ sinu ẹgún; ẹgún si ba a rú soke, o si fun u pa. Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si rú soke, o si so eso ọrọrun. Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o nahùn wipe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ