O si ṣe lẹhinna, ti o nlà gbogbo ilu ati iletò lọ, o nwasu, o nrò ìhin ayọ̀ ijọba Ọlọrun: awọn mejila si mbẹ lọdọ rẹ̀.
Ati awọn obinrin kan, ti a ti mu larada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailera wọn, Maria ti a npè ni Magdalene, lara ẹniti ẹmi èṣu meje ti jade kuro,
Ati Joanna aya Kusa ti iṣe iriju Herodu, ati Susanna, ati awọn pipọ miran, ti nwọn nṣe iranṣẹ fun u ninu ohun ini wọn.
Nigbati ọ̀pọ ijọ enia pejọ pọ̀, lati ilu gbogbo si tọ̀ ọ wá, o fi owe ba wọn sọ̀rọ pe:
Afunrugbin kan jade lọ lati fun irugbin rẹ̀: bi o si ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na; a si tẹ̀ ẹ mọlẹ, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ṣà a jẹ.
Omiran si bọ́ sori apata; bi o si ti hù jade, o gbẹ nitoriti kò ni irinlẹ omi.
Omiran si bọ́ sinu ẹgún; ẹgún si ba a rú soke, o si fun u pa.
Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si rú soke, o si so eso ọrọrun. Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o nahùn wipe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.
Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Kili a le mọ̀ owe yi si?
O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ọ̀rọ ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn miran li owe; pe ni riri, ki nwọn ki o má le ri, ati ni gbigbọ ki o má le yé wọn.
Njẹ owe na li eyi: Irugbin li ọ̀rọ Ọlọrun.
Awọn ti ẹba ọ̀na li awọn ti o gbọ́; nigbana li Èṣu wá o si mu ọ̀rọ na kuro li ọkàn wọn, ki nwọn ki o má ba gbagbọ́, ki a ma ṣe gbà wọn là.
Awọn ti ori apata li awọn, nigbati nwọn gbọ́, nwọn fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ na; awọn wọnyi kò si ni gbòngbo, nwọn a gbagbọ fun sã diẹ; nigba idanwò, nwọn a pada sẹhin.
Awọn ti o bọ sinu ẹgún li awọn, nigbati nwọn gbọ́ tan, nwọn lọ, nwọn a si fi itọju ati ọrọ̀ ati irọra aiye fun u pa, nwọn kò si le so eso asogbo.
Ṣugbọn ti ilẹ rere li awọn, ti nwọn fi ọkàn otitọ ati rere gbọ ọrọ na, nwọn di i mu ṣinṣin, nwọn si fi sũru so eso.
Kò si ẹnikẹni, nigbati o ba tàn fitilà tan, ti yio fi ohun elò bò o mọlẹ, tabi ti yio gbé e kà abẹ akete; bikoṣe ki o gbé e kà ori ọpá fitilà, ki awọn ti nwọ̀ ile ki o le ri imọlẹ.
Nitori kò si ohun ti o lumọ́, ti a ki yio fi hàn, bẹ̃ni kò si ohun ti o pamọ́, ti a kì yio mọ̀, ti ki yio si yọ si gbangba.
Njẹ ki ẹnyin ki o mã kiyesara bi ẹnyin ti ngbọ́: nitori ẹnikẹni ti o ba ni, on li a o fifun; ati ẹnikẹni ti kò ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi ti o ṣebi on ni.
Nigbana ni iya rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia.
Nwọn si wi fun u pe, Iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ duro lode, nwọn nfẹ ri ọ.
O si dahùn o si wi fun wọn pe, Iya mi ati awọn arakunrin mi li awọn wọnyi ti nwọn ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si nṣe e.
O si ṣe ni ijọ kan, o si wọ̀ ọkọ̀ kan lọ ti on ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awa ki o rekọja lọ si ìha keji adagun. Nwọn si ṣikọ̀ lọ.
Bi nwọn si ti nlọ, o sùn; iji nla si de, o nfẹ li oju adagun; nwọn si kún fun omi, nwọn si wà ninu ewu.
Nwọn si tọ̀ ọ́ wá, nwọn si jí i, wipe, Olukọni, Olukọni, awa gbé. Nigbana li o dide, o si ba ẹfufu on riru omi wi: nwọn si dá, idakẹ-rọrọ si de.
O si wi fun wọn pe, Igbagbọ́ nyin dà? Bi ẹ̀ru ti mba gbogbo wọn, ti hà si nṣe wọn, nwọn mbi ara wọn pe, irú ọkunrin kili eyi! nitori o ba ẹfufu on riru omi wi, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.
Nwọn si gúnlẹ ni ilẹ awọn ara Gadara, ti o kọju si Galili.
Nigbati o si sọkalẹ, ọkunrin kan pade rẹ̀ li ẹhin ilu na, ti o ti ni awọn ẹmi èṣu fun igba pipẹ, ti kì iwọ̀ aṣọ, bẹ̃ni kì ijoko ni ile kan, bikoṣe ni ìboji.
Nigbati o ri Jesu, o ke, o wolẹ niwaju rẹ̀, o wi li ohùn rara, pe, Kini ṣe temi tirẹ Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? emi bẹ̀ ọ máṣe da mi loró.
(Nitoriti o ti wi fun ẹmi aimọ́ na pe, ki o jade kuro lara ọkunrin na. Nigbakugba ni isá ma mu u: a si fi ẹ̀wọn ati ṣẹkẹṣẹkẹ dè e; o si da gbogbo ìde na, ẹmi èṣu na si dari rẹ̀ si ijù.)
Jesu si bi i pe, Orukọ rẹ? Ó si dahùn pe, Legioni: nitoriti ẹmi eṣu pipọ wọ̀ ọ lara lọ.
Nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe rán wọn lọ sinu ibu.
Agbo ẹlẹdẹ pipọ si mbẹ nibẹ̀ ti njẹ li ori òke: nwọn si bẹ̀ ẹ ki o jẹ ki awọn wọ̀ inu wọn lọ. O si jọwọ wọn.
Nigbati awọn ẹmi èṣu si jade kuro lara ọkunrin na, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tu pũ nwọn si sure lọ si ibi bèbe sinu adagun, nwọn si rì sinu omi.
Nigbati awọn ti mbọ́ wọn ri ohun ti o ṣe, nwọn sá, nwọn si lọ, nwọn si ròhin ni ilu ati ni ilẹ na.
Nigbana ni nwọn jade lọ iwò ohun na ti o ṣe; nwọn si tọ̀ Jesu wá, nwọn si ri ọkunrin na, lara ẹniti awọn ẹmi èṣu ti jade lọ, o joko lẹba ẹsẹ Jesu, o wọṣọ, iyè rẹ̀ si bọ̀ si ipò: ẹ̀ru si ba wọn.
Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ṣe ti a fi mu ẹniti o li ẹmi èṣu larada.
Nigbana ni gbogbo enia lati ilẹ Gadara yiká bẹ̀ ẹ pe, ki o lọ kuro lọdọ wọn; ẹ̀ru sá ba wọn gidigidi: o si bọ sinu ọkọ̀, o pada sẹhin.
Njẹ ọkunrin na ti ẹmi èṣu jade kuro lara rẹ̀, o bẹ̀ ẹ ki on ki o le ma bá a gbé: ṣugbọn Jesu rán a lọ, wipe,
Pada lọ ile rẹ, ki o si sọ ohun ti Ọlọrun ṣe fun ọ bi o ti pọ̀ to. O si lọ, o si nròhin já gbogbo ilu na bi Jesu ti ṣe ohun nla fun on to.
O si ṣe, nigbati Jesu pada lọ, awọn enia tẹwọgbà a: nitoriti gbogbo nwọn ti nreti rẹ̀.
Si kiyesi i, ọkunrin kan ti a npè ni Jairu, ọkan ninu awọn olori sinagogu, o wá: o si wolẹ lẹba ẹsẹ Jesu, o bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣai wá si ile on:
Nitori o ni ọmọbinrin kanṣoṣo, ọmọ ìwọn ọdún mejila, o nkú lọ. Bi o si ti nlọ awọn enia nhá a li àye.
Obinrin kan ti o si ni isun ẹ̀jẹ lati igba ọdún mejila, ti o ná ohun gbogbo ti o ni fun awọn oniṣegun, bẹ̃ni a ko le mu u larada lati ọwọ́ ẹnikan wá,
O wá lẹhin rẹ̀, o fi ọwọ́ tọ́ iṣẹti aṣọ rẹ̀: lọgan ni isun ẹ̀jẹ rẹ̀ si ti gbẹ.
Jesu si wipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? Nigbati gbogbo wọn sẹ́, Peteru ati awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wipe, Olukọni, awọn enia nhá ọ li àye, nwọn si mbilù ọ, iwọ si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi?
Jesu si wipe, Ẹnikan fi ọwọ́ kàn mi: nitoriti emi mọ̀ pe aṣẹ jade lara mi.
Nigbati obinrin na si mọ̀ pe on ko farasin, o warìri, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ fun u li oju awọn enia gbogbo nitori ohun ti o ṣe, ti on fi fi ọwọ́ tọ́ ọ, ati bi a ti mu on larada lojukanna.
O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, tújuka: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia.
Bi o si ti nsọ̀rọ li ẹnu, ẹnikan ti ile olori sinagogu wá, o wi fun u pe, Ọmọbinrin rẹ kú; má yọ olukọni lẹnu mọ.
Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o da a li ohùn, wipe, Má bẹ̀ru: gbagbọ́ nikan ṣa, a o si mu u larada.
Nigbati Jesu si wọ̀ ile, kò jẹ ki ẹnikẹni wọle, bikoṣe Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, ati baba on iya ọmọbinrin na.
Gbogbo nwọn si sọkun, nwọn pohùnrere ẹkún rẹ̀: o si wi fun wọn pe, Ẹ má sọkun mọ́; kò kú, sisùn li o sùn.
Nwọn si fi i ṣẹ̀fẹ, nwọn sa mọ̀ pe o kú.
Nigbati o si sé gbogbo wọn mọ́ ode, o mu u li ọwọ́, o si wipe, Ọmọbinrin, dide.
Ẹmí rẹ̀ si pada bọ̀, o si dide lọgan: o ni ki nwọn ki o fun u li onjẹ.
Ẹnu si yà awọn õbi rẹ̀: ṣugbọn o kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe wi fun ẹnikan li ohun ti a ṣe.