Jesu si mba wọn lọ. Nigbati kò si jìn si eti ile mọ́, balogun ọrún na rán awọn ọrẹ́ si i, wipe, Oluwa, má yọ ara rẹ lẹnu: nitoriti emi kò to ti iwọ iba fi wọ̀ abẹ orule mi: Nitorina emi kò si rò pe emi na yẹ lati tọ̀ ọ wá: ṣugbọn sọ ni gbolohùn kan, a o si mu ọmọ-ọdọ mi larada. Nitori emi na pẹlu jẹ ẹniti a fi si abẹ aṣẹ, ti o li ọmọ-ogun li ẹhin mi, mo wi fun ọkan pe, Lọ, a si lọ; ati fun omiran pe, Wá, a si wá; ati fun ọmọ-ọdọ mi pe, Ṣe eyi, a si ṣe e. Nigbati Jesu gbọ́ nkan wọnni, ẹnu yà a si i, o si yipada si ijọ enia ti ntọ̀ ọ lẹhin, o wipe, Mo wi fun nyin, emi kò ri irú igbagbọ́ nla bi eyi ninu awọn enia Israeli. Nigbati awọn onṣẹ si pada rè ile, nwọn ba ọmọ-ọdọ na ti nṣaisàn, ara rẹ̀ ti da.
Kà Luk 7
Feti si Luk 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 7:6-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò