Luk 7:20-50

Luk 7:20-50 YBCV

Nigbati awọn ọkunrin na si de ọdọ rẹ̀, nwọn ni, Johanu Baptisti rán wa sọdọ rẹ, wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a ma reti ẹlomiran? Ni wakati na, o si ṣe dida ara ọpọlọpọ enia ninu aisan, ati arun, ati ẹmi buburu; o si fi iriran fun ọpọlọpọ awọn afọju. Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ ròhin nkan ti ẹnyin ri, ti ẹnyin si gbọ́ fun Johanu: awọn afọju nriran, awọn amukun nrìn ṣaṣa, a sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, awọn aditi ngbọran, a njí awọn okú dide, ati fun awọn òtoṣi li a nwasu ihinrere. Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti ki yio kọsẹ̀ lara mi. Nigbati awọn onṣẹ Johanu pada lọ, o bẹ̀rẹ si isọ fun ijọ enia niti Johanu pe, Kili ẹnyin jade rè ijù lọ iwò? ifefe ti afẹfẹ nmì? Ṣugbọn kili ẹnyin jade lọ iwò? ọkunrin ti a wọ̀ li aṣọ fẹlẹfẹlẹ? wò o, awọn ti a wọ̀ li aṣọ ogo, ti nwọn si njaiye, mbẹ li afin ọba. Ṣugbọn kili ẹnyin jade lọ iwò? woli? lõtọ ni mo wi fun nyin, o si jù woli lọ. Eyiyi li ẹniti a ti kọwe nitori rẹ̀ pe, Wò o, mo rán onṣẹ mi siwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ. Mo wi fun nyin, ninu awọn ti a bí ninu obinrin, kò si woli ti o pọ̀ju Johanu Baptisti lọ: ṣugbọn ẹniti o kerejulọ ni ijọba Ọlọrun, o pọ̀ju u lọ. Gbogbo awọn enia ti o gbọ́ ati awọn agbowode, nwọn da Ọlọrun lare, nitori a ti fi baptismu Johanu baptisi wọn. Ṣugbọn awọn Farisi ati awọn amofin kọ ìmọ Ọlọrun fun ara wọn, a kò baptisi wọn lọdọ rẹ̀. Oluwa si wipe, Kili emi iba fi awọn enia iran yi wé? kini nwọn si jọ? Nwọn dabi awọn ọmọ kekere ti o joko ni ibi ọjà, ti nwọn si nkọ si ara wọn, ti nwọn si nwipe, Awa fùn fère fun nyin, ẹnyin kò jó; awa si ṣọ̀fọ fun nyin, ẹnyin kò sọkun. Nitori Johanu Baptisti wá, kò jẹ akara, bẹ̃ni kò si mu ọti-waini; ẹnyin si wipe, O li ẹmi èṣu. Ọmọ-enia de, o njẹ, o si nmu; ẹnyin si wipe, Wò o, ọjẹun, ati ọmuti, ọrẹ́ awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ! Ṣugbọn a da ọgbọ́n lare lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ gbogbo wá. Farisi kan si rọ̀ ọ ki o wá ba on jẹun. O si wọ̀ ile Farisi na lọ o si joko lati jẹun. Si kiyesi i, obinrin kan wà ni ilu na, ẹniti iṣe ẹlẹṣẹ, nigbati o mọ̀ pe Jesu joko njẹun ni ile Farisi, o mu oruba alabastar ororo ikunra wá, O si duro tì i lẹba ẹsẹ rẹ̀ lẹhin, o nsọkun, o si bẹ̀rẹ si ifi omije wẹ̀ ẹ li ẹsẹ, o si nfi irun ori rẹ̀ nù u nù, o si nfi ẹnu kò o li ẹsẹ, o si nfi ororo kùn wọn. Nigbati Farisi ti o pè e si ri i, o wi ninu ara rẹ̀ pe, ọkunrin yi iba ṣe woli, iba mọ̀ ẹni ati irú ẹniti obinrin yi iṣe ti nfi ọwọ́ kan a: nitori ẹlẹṣẹ ni. Jesu si dahùn wi fun u pe, Simoni, Mo ni ohun kan isọ fun ọ. O si dahùn wipe, Olukọni, mã wi. Onigbese kan wà ti o ni ajigbese meji: ọkan jẹ ẹ ni ẹdẹgbẹta owo idẹ, ekeji si jẹ ẹ ni adọta. Nigbati nwọn kò si ni ti nwọn o san, o darijì awọn mejeji. Wi, ninu awọn mejeji tani yio fẹ ẹ jù? Simoni dahùn o si wipe, mo ṣebi ẹniti o darijì jù ni. O si wi fun u pe, O wi i 're. O si yipada si obinrin na, o wi fun Simoni pe, Iwọ ri obinrin yi? Emi wọ̀ ile rẹ, omi wiwẹ̀ ẹsẹ iwọ kò fifun mi: ṣugbọn on, omije li o fi nrọjo si mi li ẹsẹ, irun ori rẹ̀ li o fi nnù wọn nù. Ifẹnukonu iwọ kò fi fun mi: ṣugbọn on, nigbati mo ti wọ̀ ile, ko dabọ̀ ẹnu ifi kò mi li ẹsẹ. Iwọ kò fi oróro pa mi li ori: ṣugbọn on ti fi ororo pa mi li ẹsẹ. Njẹ mo wi fun ọ, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o pọ̀ jì i; nitoriti o ni ifẹ pipọ: ẹniti a si dari diẹ jì, on na li o ni ifẹ diẹ. O si wi fun u pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ. Awọn ti o bá a joko njẹun si bẹ̀rẹ si irò ninu ara wọn pe, Tali eyi ti ndari ẹ̀ṣẹ jì-ni pẹlu? O si dahùn wi fun obinrin na pe, Igbagbọ́ rẹ gbà ọ là; mã lọ li alafia.

Àwọn fídíò fún Luk 7:20-50