Luk 7:17-23

Luk 7:17-23 YBCV

Okikí rẹ̀ si kàn ni gbogbo Judea, ati gbogbo àgbegbe ti o yiká. Awọn ọmọ-ẹhin Johanu si fi ninu gbogbo nkan wọnyi hàn fun u. Nigbati Johanu si pè awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o rán wọn sọdọ Jesu, wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a ma reti ẹlomiran? Nigbati awọn ọkunrin na si de ọdọ rẹ̀, nwọn ni, Johanu Baptisti rán wa sọdọ rẹ, wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a ma reti ẹlomiran? Ni wakati na, o si ṣe dida ara ọpọlọpọ enia ninu aisan, ati arun, ati ẹmi buburu; o si fi iriran fun ọpọlọpọ awọn afọju. Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ ròhin nkan ti ẹnyin ri, ti ẹnyin si gbọ́ fun Johanu: awọn afọju nriran, awọn amukun nrìn ṣaṣa, a sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, awọn aditi ngbọran, a njí awọn okú dide, ati fun awọn òtoṣi li a nwasu ihinrere. Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti ki yio kọsẹ̀ lara mi.

Àwọn fídíò fún Luk 7:17-23