O si ṣe ni ijọ keji, o lọ sí ilu kan ti a npè ni Naini; awọn pipọ ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si mba a lọ ati ọ̀pọ ijọ enia. Bi o si ti sunmọ ẹnu bode ilu na, si kiyesi i, nwọn ngbé okú kan jade, ọmọ kanṣoṣo na ti iya rẹ̀, o si jẹ opó: ọ̀pọ ijọ enia ilu na si wà pẹlu rẹ̀. Nigbati Oluwa si ri i, ãnu rẹ̀ ṣe e, o si wi fun u pe, Má sọkun mọ́. O si wá, o si fi ọwọ́ tọ́ aga posi na: awọn ti si nrù u duro jẹ. O si wipe, Ọdọmọkunrin, mo wi fun ọ, Dide. Ẹniti o kú na si dide joko, o bẹ̀rẹ si ohùn ifọ̀. O si fà a le iya rẹ̀ lọwọ. Ẹ̀rù si ba gbogbo wọn: nwọn si nyìn Ọlọrun logo, wipe, Woli nla dide ninu wa; ati pe, Ọlọrun si wa ibẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò. Okikí rẹ̀ si kàn ni gbogbo Judea, ati gbogbo àgbegbe ti o yiká.
Kà Luk 7
Feti si Luk 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 7:11-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò