Luk 5:30-32

Luk 5:30-32 YBCV

Ṣugbọn awọn akọwe, ati awọn Farisi nkùn si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbá awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹ, ti ẹ mba wọn mu. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn dá kò wá oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da. Emi kò wá ipè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.

Àwọn fídíò fún Luk 5:30-32