Luk 4:33-37

Luk 4:33-37 YBCV

Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu, ẹniti o li ẹmi aimọ́, o kigbe li ohùn rara, O ni, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ iṣe; Ẹni Mimọ́ Ọlọrun. Jesu si ba a wi, o ni, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade lara rẹ̀. Nigbati ẹmí eṣu na si gbé e ṣanlẹ li awujọ, o jade kuro lara rẹ̀, kò si pa a lara. Hà si ṣe gbogbo wọn nwọn si mba ara wọn sọ, wipe, Ọ̀rọ kili eyi! nitori pẹlu aṣẹ ati agbara li o fi ba awọn ẹmi aimọ́ wi, nwọn si jade kuro. Okikí rẹ̀ si kàn nibi gbogbo li àgbegbe ilẹ na yiká.

Àwọn fídíò fún Luk 4:33-37