Luk 3:5-17

Luk 3:5-17 YBCV

Gbogbo ọgbún li a o kún, gbogbo òke nla ati òke kekere li a o tẹ-bẹrẹ; wíwọ li a o ṣe ni títọ, ati ọ̀na palapala li a o sọ di kikuna; Gbogbo enia ni yio si ri igbala Ọlọrun. Nigbana li o wi fun ọ̀pọ awọn enia ti o wá lati baptisi lọdọ rẹ̀ pe, Ẹnyin iran paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀? Nitorina ki ẹnyin ki o so eso ti o yẹ fun ironupiwada, ki ẹ má si ṣe bẹ̀rẹ si iwi ninu ara nyin pe, awa ni Abrahamu ni baba: ki emi ki o wi fun nyin, Ọlọrun le gbe ọmọ dide fun Abrahamu ninu okuta wọnyi. Ati nisisiyi pẹlu, a fi ãke le gbòngbo igi na: gbogbo igi ti kò ba so eso rere, a ke e lulẹ, a si wọ́ ọ jù sinu iná. Awọn enia si mbi i pe, Kini ki awa ki o ha ṣe? O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li ẹ̀wu meji, ki o fi ọkan fun ẹniti kò ni; ẹniti o ba si li onjẹ, ki o ṣe bẹ̃ pẹlu. Awọn agbowode si tọ̀ ọ wá lati baptisi lọdọ rẹ̀, nwọn si bi i pe, Olukọni, kili awa o ha ṣe? O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe fi agbara gbà jù bi a ti rán nyin lọ mọ́. Awọn ọmọ-ogun si bère lọdọ rẹ̀, pe, Ati awa, kili awa o ṣe? O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe huwa ipá si ẹnikẹni, ki ẹ má si ṣe rẹ ẹnikẹni jẹ; ki owo onjẹ nyin to nyin. Bi awọn enia si ti nreti, ti gbogbo wọn si nrò ninu ara wọn nitori Johanu, bi on ni Kristi bi on kọ́; Johanu dahùn o si wi fun gbogbo wọn pe, Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin; ṣugbọn ẹniti o lagbarà ju mi lọ mbọ̀, okùn bàta ẹsẹ ẹniti emi ko to itú: on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin: Ẹniti atẹ rẹ̀ mbẹ li ọwọ́ rẹ̀, lati gbá ilẹ ipaka rẹ̀ mọ́ toto, ki o si kó alikama rẹ̀ sinu aká; ṣugbọn ìyangbo ni yio fi iná ajõku sun.

Àwọn fídíò fún Luk 3:5-17